Oluwa li Oluso-agutan mi; emi ki yio se alaini.
O mu mi dubule ninu papa-oko tutu: o mu mi lo si iha omi
didake roro.
O tu okan mi lara: o mu mi lo nipa ona ododo nitori oruko re.
Nitoto, bi mo tile nrin larin afonifoji ojiji iku, emi ki yio
beru ibi kan: nitori ti Iwo pelu mi: ogo re ati opa re nwon ntu mi ninu.
Iwo te tabili onje sile niwaju mi li oju awon ota mi: iwo da
ororo si mi li ori: ago mi si kun akunwosile.
Nitoto, ire ati anu ni yio ma to mi lehin li ojo aiye mi
gbogbo: emi o si ma gbe inu ile Oluwa lailai.
Amin.
No comments:
Post a Comment