A - Alaafia fun o.
B - Buburu kan ki yoo subu lu o.
D - Dugbedugbe ibanuje ko ni ja le o l'ori.
E - Ebi o ni pa o ninu odun yi.
E - Ekun, ose ko ni je tire.
F - Funfun aye re ko ni dibaje.
G - Gunnungun ki ku l'ewe, wa dagba – wa d'arugbo.
GB - Gbogbo idawole re a y'ori si rere.
H -Hausa,Yoruba,Ibo,gbogbo eya ati eniyan kaakiri agbaye ni yo koju si o se o loore.
I - Iwaju, iwaju l'opa ebiti re yo ma re si.
J - Jijade re, wiwole re, o ni k'agbako.
K - Kukuru abi giga, osi ati ise ko ni je tire.
L - Loniloni wa r'aanu gba.
M - Monamona ati ara Olorun yoo tu awon ota re ka.
N - Naira, Euro, Dollar, Pound,Yen,Yuan,gbogbo owo ati oro kaakiri agbaye pelu omo alalubarika ati alaafia yio mu o l'ore, won o si fi ile re se ibugbe.
O - Ojurere ati aanu yoo ma to o leyin ni ojo aye re gbogbo. O O - Ojo ola re a dara.
P - Panpe aye o ni mu o t'omotomo.
R - Rere ni agogo aye re o ma lu nigbagbogbo.
S - Suuru pelu itelorun ninu oro at'alaafia yoo ba o kale.
S - Sugbon ati abawon aye re ti poora loni.
T - Tomotomo, t'ebitebi, t'iletile o ni d'ero eyin.
U - U ki s'awati lede Ijesha; a o ni fi o s'awati laarin awon eniyan. Ulosiwaju (ilosiwaju), userere
(iserere), ati ubukun(ibunkun) yio je tire.
W -Wa ri ba ti se, wa r'ona gbe gba.
Y - Yara ibukun, ire, ati ayo ailopin loo ma ba e gbe titi ojo aye re......
AMIN (ASE EDUMARE)